Àṣà Ìgbéyàwó

Àṣà Ìgbéyàwó

Ìgbéyàwó jẹ ìsodọ̀kan ọkùnrin àti  obìnrin tí ó ti bàlágà,láti jo máa gbé papọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkọ àti aya.
Tí aba fẹ́ kí ìgbéyàwó wáyé ní ilè Yorùbá óní àwọn ìlànà àá tẹ́lẹ̀. Àwọn ìlànà náà rẹ:

1) Ìfojúsọ́de:  èyí máa ń wáyé nígbà tí ẹbí kan bá ń wá ìyàwó fún ọmọ wọn ọkùnrin tí ó ti tó ìyàwó gbé sílẹ́.

2) Ìwádìí: èyí ni ṣíṣe ìwádìí ìdílé tí ọmọkùnrin tí fẹ́ gbé ìyàwó, nítorí rí wípé oríṣiríṣi ìdílé ló wà, àwọn ìdílé kan wà tí àrùn máa ń yọwón lénu fún àpẹẹrẹ; WÁRÁPÁ, ÀBÍSÍNWÍN abbl. Ìdílé míràn wo kìí dàgbà tí wọ́n fi má ń kú, ìwádìí ó tún tẹ̀ síwájú láti mọ irúfé ènìyàn tí ọmọbìnrin náà jé bóyá asa ọmọ ni, bóyá oní kébekèbe ni, lẹ́yìn èyí ni wọn yóò lọ bẹ̀rẹ̀ lọ́wọ́ ifá Gẹ́gẹ́bí Ẹlẹ́rìí-ìpín tí kò lè puró, gbogbo àṣírí ọjọ́ ọ̀la ìgbéyàwó náà ni yóò hàn gbangba lọ́dọ̀ ifá olókùn.

3) Alárinà: èyí jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ìlànà tí wọ́n fi ń fẹ́ ìyàwó láyé, ọkùnrin tàbí obìnrin tí ó sún mọ́ ọmọbìnrin,leyii tí ó lee jẹ́ ọ̀rẹ́ tàbí mọ̀lébí obìnrin òun ni ẹni tí ó ń yẹ ọ̀nà fún ọmọkùnrin tí ó fẹ́ fẹ́ ìyàwó kí àwọn méjèèjì tó pàdé.

4) Ìsíhùn: èyí ni wípé ọmọbìnrin ti gbọ́ ó sì ti gbà láti jé àfèsónà ọmọkùnrin náà. Ọmọkùnrin yìí ó wá san owó Ìsíhùn fún àwọn ẹbí ọmọbìnrin yìí kì o tó lè máa bá ọmọbìnrin náà sọ̀rọ̀.

5) Ìtọrọ: Àwọn òbí àti díè nínú ẹbí ọmọkùnrin yóò lọ si ilé òbí ọmọbìnrin  láti sọ fún wọn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ sí ọmọ wọn obìnrin láti fé fún ọmọ àwọn. Àwọn òbí ọmọbìnrin yìí ó dájọ́ fún àwọn ẹbí ọmọkùnrin pé kí wọ́n padà wá , ó lè jẹ́ lẹ́yìn ọjọ́ méje tàbí jù bẹẹ lọ, àwọn ẹbí ọmọbìnrin yìí náà lọ ṣe ìwádìí nípa irú ìdílé tí ọmọkùnrin náà tí jáde, irú ènìyàn tí ó jé, wọn yíò tẹ síwájú láti ṣe ìwádìí lọ́wọ́ ifá olókùn bí ọjọ́ iwájú ìgbéyàwó náà yíò ṣe rí, tí ìwádìí wọn ba yọrí sí rere gbígbọ́ àti gbígbà tí àwọn òbí ọmọbìnrin gba láti fi ọmọ wọn obìnrin fún ẹbí ọkùnrin gẹ́gẹ́ bí aya ni Yorùbá ma ń pè ní BÀBÁ GBÓ ÌYÁ GBÀ.

6) ìdána : Èyí ni fífé obìnrin ní isu l’ọka, kíkó àwọn ẹrù ìdána lọ sí ilé òbí obìnrin gẹ́gẹ́ bí àṣà Yorùbá, àwọn nǹkan ìdána bíi : isu ,obì , orógbó ,aadun, ataare ,ìrèké, iyọ̀ , epo , oyin,ẹja ọsan, àti owó-orí ìyàwó.

7)Ayẹyẹ -Ìgbéyàwó : Ọjọ́ ayẹyẹ ìgbéyàwó jẹ́ ọjọ́ iyì àti ẹ̀yẹ fún ìyàwó, ọkọ ìyàwó àti àwọn mọ̀lébí wọn. Ní ìrólé ọjọ́ tí ìyàwó ó re ilé ọkọ rẹ, lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti múra tán yóò lọ dágbére fún àwọn òbí rẹ àti àwọn mọ̀lébí, àkókò yìí ni ìyàwó ó máa sún ẹkùn ìyàwó láti dágbére, láti fi dúpẹ́ àti láti fi gba àdúrà lẹ́nu àwọn òbí àti mọ̀lébí rẹ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ó sì máa tẹ̀le le bí ó ti ń sun ẹkún ìyàwó kiri wọn ó máa rèé lé’kún.

Àsálé ni yóò tó dárí padà sí odò àwọn òbí rẹ, lẹ́yìn ìwúre bàbá yóò fà á ìyàwó lé ọwọ́ obìnrin tí ó jé àgbà nínú àwọn ẹbí ọkọ lọ́wọ́, àwọn ìyàwó ilé àti àwọn ọ̀rẹ́ ìyàwó yóò fi ìlù àti orin tẹ̀lẹ lọ sí ilé ọkọ rẹ.
Ọkọ ìyàwó tí gbọdọ̀ kúrò ní ilé kí wọn tó mú ìyàwó rè dé, eèwọ̀ ni ní ilé Yorùbá ìyàwó kò gbọdọ̀ bá ọkọ rẹ nílé ni alé ọjọ́ ìgbéyàwó wọn, lẹ́yìn tí wọ́n bá ti mú ìyàwó wọlé tán tí ọkọ ni ọkọ ìyàwó ó too wọlé wá.
Àwọn ìyáalé ìyàwó yóò bu omi tutù sí Ẹsẹ̀ ìyàwó tuntun lenu ọ̀nà àbáwọlé, ìgbàgbọ́ àwọn Yorùbá ni pé kí ìyàwó lè fi Ẹsẹ̀ èrò wọlé ọkọ rẹ̀. Lẹ́yìn èyí wọn yóò dojú igbá gbígbe délè tí ìyàwó tuntun ó fi Ẹsẹ̀ fo, àwọn Yorùbá ni ìgbàgbọ́ pé iye ọ̀nà tí ìgbà yìí fo sí ní iye ọmọ tí ìyàwó yóò bí, tí ó bá wù ú ó lè má bí tó bẹ́ẹ̀ tàbí kí ó bí ju bẹẹ lọ.

8) Ìbálé: Ọkọ -ìyàwó àti ìyàwó á dìjọ ni ibalopọ fún ìgbà àkókò ni alé ọjọ́ ìgbéyàwó wọn láti mò bóyá ìyàwó tuntun yìí ò tí mọ ọkùnrin rí. Àwọn òbí ọkọ yóò tité aṣọ funfun sí orí ibùsùn nínú yàrá ọkọ ìyàwó láti fi gba ìbálé ìyàwó rè. Iyì ńlá ni fún àwọn òbí ìyàwó tí ọkọ rẹ bá nílé, ó túmọ̀ sí wípé ọmọbìnrin náà kò tíì mọ ọkùnrin rí. Odidi agbè ẹmu tàbí odidi páalí ìsáná, ìyàn àti ọbẹ̀ tí ó dára ní àwọn ẹbí ọkọ ìyàwó yóò gbé lọ fún àwọn òbí ìyàwó laarọ kùtùkùtù ọjọ́ kejì láti fi dúpẹ́ lọwọ wọn wípé odidi ni wọ́n bá ọmọ wọn, èyí ni oúnjẹ ìbálé, ìyàwó yóò tún gba owó ìbálé tíì ṣe ọ̀kẹ́ méjì lọ́wọ́ ọkọ rẹ̀.

Ìtìjú àti àbùkù ni fún ìyàwó tí ọkọ rẹ kò bá nílé, ìlàjì agbè ẹmu tàbí ìlàjì páalí ìsáná ni àwọn òbí ọkọ ìyàwó yóò fi ránṣé sí àwọn òbí ìyàwó tí ọkọ rẹ̀ kò bá nílé láti lè jẹ́ kí wọ́n mọ̀ wípé ọmọ wọn tí mọ ọkùnrin rí.

9) Ìkòrún: Ọjọ́ karùn-ún tí ìyàwó wọlé ọkọ rẹ̀ ni yóò tó jáde síta,láti ṣe iṣẹ́ -ilé àkókò àti láti lọ kí àwọn ẹbí ọkọ rẹ̀. Ọjọ́ yìí náà ni yóò jẹ́ ìgbà àkókò tí yóò dáná oúnjẹ fún ọkọ rẹ̀.  

#EdeYorubaRewa

Leave a Reply

Your email address will not be published.