Àrọ̀nì ò wálé oníkòyí ò simi ogun lílọ

Ẹ kú dédé àsìkò yìí gbogbo olólùfẹ́ ojú ìwé yìí, látàrí ìbéèrè tí mo béèrè tí kò si sii ẹni tí ó gbà á.

Ìbéèrè náà ni wípé ìtàn wo ló rọ mọ òwe Yorùbá kan tí ó sọ wípé “#àrònì ò wálé oníkòyí ò simi ogun lílọ”

Ìtàn náà rẹ ooo, ẹkú ojú lọ́nà

#Apá kìíní

Ní ayé àtijó ní ìlú Ọ̀yọ́, wọn ma ń ṣe oríṣiríṣi àwọn ọdún nígbà náà ṣùgbọ́n kí wọn tó ṣe ohunkóhun wá bẹẹ ifá lọ́wè. Nígbà tí ọdún yí wọlé, Oba Alaàfin ránsé pe Babaláwo pé kí ó wá dá ifá Odún.  Babaláwo dí’fá, ifá fọ irẹ, ifá ni aboyún ilé ábíwéré, Àgàn a t’ọwọ ààlà bọ’sùn, eku a ké bí eku, ẹyẹ a ké bí ẹyẹ, ọmọ ènìyàn a fọ’hùn bí ènìyàn ṣùgbọ́n ooo ìkìlò ń bẹẹ ooo, wọn kò gbọdọ̀ gba àlejò lákòókò ọdún yí nítorí ewu ń lá wá níbẹ̀ tí wọn bá gba àlejò.

Oníkòyí jẹ ààyò ọba Ọ̀yọ́ Aláàfin nígbà náà látàrí àwọn ìrànlówó tí oníkòyí ṣe f’ọba.

Oníkòyí lo fẹ́ ṣe ayẹyẹ, ó si pe gbogbo àwọn ènìyàn kí wọn wá bá ṣe ayẹyẹ náà dé bi wípé ọmọ ọba bìnrin Aláàfin Òyo tí orúkọ ń jẹ “Kúlúwé” náà lọ, inú gbogbo àwọn ènìyàn dùn, wónjó, wón yò, wọn jẹ wọn sì tún mú pẹ̀lú..

Ọkùnrin kan wà tí orúkọ ń jẹ “Àrònì”, Àrònì sí jẹ alágbára ènìyàn tí wọn mọ káàkiri, ní àkókò tí ayẹyẹ Oníkòyí ń lọ lọ́wọ́, Àrònì náà wá lèyí tó jẹ́ wípé Àjòjì ni ìlú Ọ̀yọ́, ó pa oríṣiríṣi idán – fún àpere  ó kó yerùpè ilè jọ, ó p’ọfọ, ó pe ògèdè, yerùpè náà sì di ẹtù ìbọn; ó tún kó ọparun jọ ó p’ọfọ, ó pe ègèdè ọparun náà sii di ìbọn; ó la enu òhòò, Ò da igba ofà síle….

Ẹ yí wa jẹ́ kàyéfì fún Oníkòyí, Oníkòyí  sii gba Àrònì sọdọ látàrí agbára tí ó ní pé yio lè má rán ohun lọ́wọ́ tí àwọn bá lọ sí ogun

Àrònì f’ojú kan Kúlúwé ti se omoba bìnrin Aláàfin Òyo, ó ṣì sọ fún oníkòyí pé ohun nife re – Kúlúwé jé arẹwà lóbìnrin; Oníkòyí sọ fún Àrònì wípé ọmọ Oba ìlú Ọ̀yọ́ Aláàfin ni Kúlúwé se, àmọ́ ohun yio ba sọ̀rọ̀. Pèlú abgára àti ète Àrònì, Oníkòyí bá kúlúwé ní gbólóhùn, Kúlúwé sì gbà si lénu.

Nígbàtí ódi alé, Àrònì àti kúlúwé ni wón jo sùn sí inú yàrá, iná nlá so nínú ilé l’ógànjó òru, Àrònì pèlú agbára rè pòórá, sùgbón Kúlúwé tí íse Omo Oba Aláàfin Òyo sì jónámónlé.

Inú oníkòyí bàjé gidigidi látàrí bí kúlúwé tí jóná mo ilé, ìrònú ńlá bá Oníkòyí látàrí ìsèlè yí pèlú wípé báwo ni wón ti se’ma tú Oba l’ófò.

Gbogbo awon àgbàgbà wá fi orí k’orí  pé kí wọn ràn Àyàn lọ kí ó lọ túfò nítorí pé ogun kii pa àwọn oní’lù.

Àyàn náà sí lọ sí ààfin ọba Ọ̀yọ́, ó si ńlu ìlù tí ó ń sọ wípé:

#Kúlúwé jóná mọ’lé
#Kúlúwé jóná mọ’lé
#Kúlúwé jóná mọ’lé
#Kúlúwé jóná mọ’lé
#Kúlúwé jóná mọ’lé

Aláàfin gbọ́, inú bíi, o si sọ wípé kí wọn lọ gbé oníkòyí wá, wọn sii tí mọọ inú túbú, lẹ́yìn ọjọ́ díè àwọn ìjòyè Ọ̀yọ́ bẹẹ Aláàfin pé kí ó tú oníkòyí sílè, ó gbọ sí wọn lẹ́nu, ó sii pàṣẹ kí wọn tú oníkòyí sílè.

Inú oníkòyí dùn, ó sii sọ fún Aláàfin pé bí ohun ṣe ń lọ yíò Àrònì ni ohun wá lọ, bí ohun kò bá sii rí Àrònì, òhun kò ní wálé, àti wípé gbogbo ìlú tí ohun bá kan kí ohun tó rí Àrònì gbogbo wọn lóhùn máa kogun ja, tí òhun sí ma kó erú kó erù fi’sin  Oba láàfin.

Láti ìgbà náà ni oníkòyí ti’njagun káàkiri tí ó sì ńwá Àrònì kiri títí di òní.

#Ìdí rẹ nìyí tí òwe Yorùbá fi sọ wípé “Àrònì ò wálé oníkòyí ò simi ogun lílọ”

Narrated by Akano Kazeem Ìdòwú

#Written by Semiat Olufunke Bello(Wúràọlá)

One Comment on “Àrọ̀nì ò wálé oníkòyí ò simi ogun lílọ”

Leave a Reply

Your email address will not be published.