Ẹsẹ IFÁ
Apá Kínní ÒTÚÁ MÉJÌ
Wútùwútù yáákí;
Wútùwútù yám̀bèlé,
Ká súré pátápirá,
Ká fẹ̀wù àlàárì fọnkun àmọ́di,
Lékèélékèé, ẹyẹ ìmọ̀le,
Bó bá ṣí lórí ọ̀pọ̀tọ̀,
A bà sórí òrom̀bó,
A máa fi gbogbo ara kéwú eléwú kiri,
A díá fún ọ̀rúnmìlà,
Ifa ń sunkún òun ò rọ́mọ bí.
wọ́n ní ẹbọ ní ó wàá rú
Ó sì rú u.
Wón ní ó réku méjì olúwéré
Kó rẹ́ja méjì abìwẹ̀gbàdà,
Obídìẹ méjì abẹ̀dọ̀ lùkẹ́lùkẹ́,
Ewúrẹ méjì abàmú rẹdẹrẹdẹ,
Ẹinlá méjì tó fìwo ṣòṣùká.
Gbobgo rẹ̀ náà ló rú.
Ìgbà tí Ọ̀rúnmìlà ó kọ̀ọ́ bí,
Ó bí Gánḿbí.
Ìgbà tí ó tùún bí,
Ó bí Kálítù,
Ìgbà tí ó tùún bí,
Ó bí Dáúdù,
Èyí tíí ṣọmọ ìkẹyìin wọn léńje.
Ikú kò pa wọ́n
Àrùn kò ṣe wọ́n,
Ìgbà tí wọ́n dàgbà tán,
Ọ̀rúnmìlà kọ́ wọ́n ní dídá ọwọ́,
Wọ́n mọ̀ ọ́n dá.
Ó́ kọ́ wọ́n létìtẹ̀ alẹ̀,
wọ́n mọ̀ ọ́n tẹ̀.
Ó́ kọ́ wọ́n ní ọ̀karara ẹbọ,
wọ́n mọ̀ ọ́n ha.
Nígbà tó dọjọ́ kan,
Ni wọ́n bá ré agbádá bàbáa wọn,
Wọ́n ré gèlè ìyá wọn;
Wọ́n wọ agbádá náà;
Wọ́n sì wé gèlè náà sórí bàǹtùtù.
Wọ́n na igi mẹ́rin sílẹ̀ níbùúníbùú
Wọ́n wáá kó sí ààrin àwọn igi náà,
Wọ́n ń sẹnu wújẹ́wújẹ́;
Wọ́n ń forí kanlẹ̀,
Wọ́n ń dìde.
Wọ́n ń kúnlẹ̀
Wọ́n sì ń nàró
Bàbáa wọn ṣá ń wò wọ̀n ni.
Wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ lẹ́ẹ̀maàrúnmárùún lójoojúmọ́.
Ó wáá rántí Ifá
Tí àwọn awoo rẹ̀ẹ́ kì fún un,
Kò bá wọn jà
kẹ̀ẹ̀kẹ̀ẹ̀ kiní yìí ń wọ̀ wọ́n lára
Ìgbà tó yá,
Wọ́n wáá mú un bí iṣẹ́