ÌTỌ́JÚ
Àdán dorí kodò o ń wòse ẹyẹ,
ẹjẹ́ka ronún wò káwo báyé ti ń lọ,
káwo gbogbo o n tí ó n selẹ̀ nílé lòko.
Bàbá r’oko olówó nítorí àti t’ómọ,
ìyá gbàárù gbàárù k’ọmọ ba lè lẹ́kọ́,
ọmọ dẹni tí ń gbowó gọbọi lẹnu isẹ́ Ọba,
ówá ń tàpá gbàngbàn sí bàbá tóbi lọ́mọ,
o n wóyá sùnsùn bí àkísà ẹlẹ́gbin,
ẹ̀yin ọmọdé ẹgbọ́, ẹtọ́jú àwọn òbí yín
Nítorí àwọn ná wò yín dàgbà.