OÚNJẸ

OÚNJẸ

Mo gbà oúnjẹ gbó,
oúnjẹ ni alákòóso ara,
Oúnjẹ ní ọ̀rẹ́ àwò
Iyán l’oúnjẹ,
Ọkà Lógún,
Àìní rárá lá ń jèko
Ké ẹnu má di lè ní ti gúgúrú
Nínú Ìpàdé  oúnjẹ,
Iyán làgbà,
Àmàlà nigbá kejì
Níjó tí iyán níyàwó,
Ọbẹ̀ ègúsí níyàwó,
Nijo tí Àmàlà fẹ́ ìyàwó,
Ewédú ní o yàn layoo,
Àkàrà aya àkàsù
Ólè arẹwà Onifẹ ẹ̀kọ mímú,
Dundun ko kere, Ojoba nigberiko
Dodo naa ko rehin, O joba ni ileto
Alágbára ni ata jẹ,
Alubosa gbajúmò,
Borokini olórò ni ègúsí jẹ,
Nínú gbogbo eléyìí,
Omi àti àtẹ̀gùn náà oúnjẹ ni,

Kí Èdùmàrè má fi ebi pawá(Àmín láṣẹ èdùmàrè)

Leave a Reply

Your email address will not be published.