ÀÌRÍ’ṢẸ́ ṢE

ÀÌRÍ’ṢẸ́ ṢE

Ẹni tó jí láàárọ̀,
To jáde nílé,
Tó rí bìkan gbà lọ,
Yálà iṣẹ́ ojúmọ́ tàbí toṣù,
Tó dìrọ̀lẹ́ tó padà wálé,
Tó rọ́wọ́ ti bàpò,
Tàbí to dị ìparí oṣù,
Tó jẹ́ ṣa fẹ́tọ̀ọ́ rẹ̀,
Kò mọ ohun tí olúwa ṣe fún ohun,
Jẹ́ kó dúró nílé lọ́ṣẹ̀ kan wò,
Kó wá máa dáhùn ìbéèrè,
“ṣe ko si? Ẹ ẹ̀ lo sí ibi iṣẹ́ ni? “
Ìtìjú ńlá lèyí fún ẹni tí ó mọ inú rò,
Iṣẹ́ wọn lóde lásìkò yìí,
Bẹ́ẹ̀ ọ̀nà ọ̀fun, ọ̀nà ọ̀run,
Àìníṣẹ́ lọ́wọ́ ní mú ni jalè,
Ní mú ni hùwà àìtọ́,
Ọwọ́ to si dilẹ̀ ni Èṣù ń bẹ̀ níṣẹ́,
Ó jáde ilé ìwé gíga, osìnru ìlú, ó padà wálé,
Lati tún wá jókòó tí àwọn òbí tó yẹ kí wọn máa jẹun rẹ,
Àwọn ló tún ń bọ́ ẹ, tí wọn ń ra aṣọ sí ẹ lọ́rùn,
Ìgbàwo ni èròkèrò kò ní wá sí ọkàn ọmọ bẹẹ,
Tí irú ọmọ bẹ́ẹ̀ ò bá ní ìgbàgbọ́,

Èyin ìjọba àpapọ̀ orílè èdè Nàìjíríà àti ìjọba ìpínlè ẹ Dákun ẹ báwa wá ǹkan ṣe sọ́rọ̀ Àìrí’ṣẹ́ ṣe àwọn ọ̀dọ́ kí orílè èdè wa leè tẹ síwájú……

Leave a Reply

Your email address will not be published.