AláyéLúwà
Ìwòfà pàdé ọba lọ́nà,
Ó gbàdúrà kẹ́lẹ́ kẹ́lẹ́,
Pé bóyá orí a ṣé,
Òun náà a dépò ọba,
Láì mọ̀ wípé,
Orí adé ò jẹ́rù ọba o fúyé,
Lotito ipò ọba dára,
Ipò kábíyèsí dára púpọ̀,
Ṣùgbọ́n ìdààmú ìdí rẹ̀ pọ,
Ọba ò lẹ́sìn,
Bọ́dún Mùsùlùmí dé,
Ó dí dandan kó bá wọn ṣe,
Bí àwọn kirisititeni ń sọdún,
Ó gbọdọ̀ báwọn ṣe,
Bí ẹṣin àbáláyé ṣe tiẹ̀ ó gbọdọ̀ kó pá,
Nítorí ó ní ipa pàtàkì láti kó,
Ọ̀pọ̀ nnkan lo wa,
Tí ọba ó gbọdọ̀ ṣe,
Torí ipò ẹlẹgẹ́ tó dì mú,
Gbogbo ojú ni n bẹ lára ọba,
Ọba o lè sẹ̀yọ́ ní gbangba,
Ọba kìí jẹun ní ìta,
Ọba ò gbọdọ̀ sè yí ṣe tọ̀hun,
Bí o tilè jẹ́ pé,
A ó mọ bí wọn tíì ń sìnkú ọba,
Ó dájú wípé ọba kìí sùn bí i mẹ̀kúnnù,
Ipò ọba dára ṣùgbọ́n ohùn tó rọ mọ pọ̀,
Ìdí rẹ ni yìí tí Yorùbá má fi ń sọ wípé
#Ilésanmíwọnlódùnjoyèlọ.
Ẹ jẹ́ kí a má dúpẹ́ ni gbogbo ipò tí a bá ara wa.
Èdùmàrè jẹ́ kí gbogbo ọba ilé Yorùbá pé bí mópé tí ń pé, Kádé pé lórí gbogbo wọn, kí bàtà pé lẹ́sẹ̀ wọn, kí ìrùkèrè wọn di ọkini.
#ÀmínÀṣẹÈdùmàrè