ẸNU
Ọmọ aráyé ẹ jẹ́ ká ṣọ́ra fẹ́nu
Ẹnu ní í lani
Ẹnu ní í pani
Ẹnu ní jin ni sọ́fìn
Ẹnu làá fi ń tún ènìyàn ṣe
Ẹnu la fi ń bá ènìyàn jẹ
Ẹnu wa ò ní pa wá
Kí o tó fi ẹnu sọ ohunkóhun
Ẹ jẹ́ ká ronú jinlẹ̀
Torí bí ọ̀rọ̀ bá ti balẹ̀
Kò ṣe dápadà mọ
Wọ́n ni ká bọ eégún ilé
A bọ eégún ilé
Wọ́n ní ká bọ òrìṣà ọjà
A Bọ òrìṣà ọjà
Wọ́n ní ká bọ olúbọ̀bọ̀tiribọ̀ baba ẹbọ
Ǹjẹ́ kí ni olúbọ̀bọ̀tiribọ̀ baba ẹbọ?
Wọ́n ni ẹnu ní i jẹ́ bẹ́ẹ̀
Ǹjẹ́ kí ni wọ́n ní bọ n’ife?
Ẹnu ní wọ́n ń bọ n’ife
Èdùmàrè ò ní jẹ́ kí ẹnu wá pa wa oooo
Orin
Ọmọ kékeré ẹnu lẹbọ ooo
Ẹnu lẹbọ
Àgbàlagbà ẹnu lẹbọ ooo
Ẹnu lẹbọ
Ẹnu ló wọ́lé e bàbá kan
Ẹnu lẹbọ