IGI Ọ̀PẸ

IGI Ọ̀PẸ

Òjìji fì í
Aró’gba aṣọ má balẹ̀
Èmi ọ̀pẹ ní jẹ́ bẹ́ẹ̀
Mo wúlò púpọ̀ fún ọmọ aráyé
Àsàdànù kò sí nínú ẹ̀yà ara mi
Igi mi wúlò fún afárá
Lórí ìsun àti odò kékeré
À ń fi imọ̀ mi kọ́lé
Ọwọ́ ń bẹ lára mi
Lèyí tí a fi ń jalè
Ara mi ni àwọn akọ̀pe
Tí ń da ẹmu
Tó ni èròjà kojú o mọ́le kedere nínú
Ara ẹyìn la tí ń ri epo
Ihá tàbí ògùsò kò gbèyín
Èkùrọ́ mi náà  ló ń di àdíẹ̀yan
Ẹẹ́san náà o gbèyín Lèyí tí ó dára fún iná dídá
Ìkẹ̀tẹ́ náà wà lára ohun tí mó ń fún aráyé
Eérú ṣoṣo mi wúlò fún ọsẹ dúdú
Igi wo ló wúlò tó ọ̀pẹ?
Kí ó yọ jú kafaga-gbága
Kí n lahùn fún irú igi bẹ́ẹ̀
Ọ̀pẹ! Ọ̀pẹ!! Ọ̀pẹ!!!
Igi to fi gbogbo ara ṣọwọ́.
Èdùmàrè jẹ́ ká wúlò bíi igi ọ̀pẹ…

Leave a Reply

Your email address will not be published.