Ìtàn Bàbá Alàjọ Sómólú

Alphaeus Taiwo Olunaike jẹ́ orúkọ  tí gbogbo ọmọ orílè èdè Nàìjíríà o mọ, ṣùgbọ́n tí wọn ba gbo Baba Alàjọ Somolu,
Gbogbo la mọ orúkọ náà.
Bàbá Alàjọ Sómólú jẹ́ ẹni tí wọn bí  ígbátí ewu ń lá ni ìlú wọn, bí ìtàn ṣe fi yẹ wa. Wọn bí Taiwo Olunaike ọmọ
Alphaeus ni ọjọ́ kẹrindínlógún oṣù Kẹ̀sán ọdún 1915 ni ìlú kan tí wọn pè ní Isan Oyin (tí wọn pè ní Isonyin lakoko yí) ìlú náà wá létí Ìjẹ̀bú Musin àti Ìjẹ̀bú Ode ni Ìpínlẹ̀ Ógùn. Wọn gbọ́ igbe àwọn ọmọ tuntun láti ọ̀dọ̀ arábìnrin kan tí orúkọ rẹ ǹjẹ́ Grace Okuromiko Olunaike tí o bímọ ọmọ tí a ń pè ní etaoko.
Kété tí wọn sọ fún ohun àti ọkọ rẹ pé ọmọ mẹta lo bí ní ẹkan náà, inu wọn bàjé, wọn sì bu sekun, iporuru gba ọkàn wọn nítorí pé wọn etaoko sí nkan abàmì ni ìlú wọn, ẹni èyí tó jẹ́ wípé wọn a ìkan nínú àwọn ọmọ náà fún ẹbọ.
Ṣùgbọ́n ìtàn fi yẹ wá pé gbogbo àwọn tí ó lọ́wọ́ nínú pípa ọkàn lára àwọn ọmọ náà o kije tí wọn fi ta téru ni pa.
Nígbàtí tí wọn pé ọmọ ọdún merin bàbá wọn kú, ìyá àti ẹ̀gbọ́n obìnrin tí wọn ní lọ tọju wọn, ṣùgbọ́n laipe laijina ọmọ Kehinde náà kú lèyí tí ó jẹ pé Taye nìkan ló kù.
Ohun náà sì ni ẹni tí mo fé sọ nipe rẹ.

Taiwo Olunaike jẹ́ ọmọ ọdún merin nígbà tí baba wọn kú, ó bere ilé ìwé alákòbẹ̀rẹ̀ ni Emmanuel Primary School, Ìjẹ̀bú Isonyin. 
Kò parí ẹ̀kọ́ rẹ tí ẹ̀gbọ́n baba rẹ Torimoro fi mú lọ sí ìlú Èkó láti Tẹsiwaju nínú ẹ̀kọ́ rẹ.
Orí rẹ ko yọ lọ́wọ́ fífi rúbọ ní ọdún 1927, nígbà tí ó dé ìlú Èkó wọn fi sí ilé ìwé St. Johns School, Aroloya.
Láti ibè ó wọ ilé ìwé Christ Church Cathedral , ní ìlú Èkó Lagos, ó sì ṣe tán ni ọdún 1934.
Lẹ́yìn ọdún méjì tí ó ti parí ẹ̀kọ́, ẹ̀gbọ́n baba rẹ lọ fi sì ẹnu ẹ̀kọ́ ìṣe aṣọ ríran, ó sì kó ìṣe náà fún ọdún mẹsan kí ó tó gbà òmìnira.
Ó bẹ̀rẹ̀ si rán aṣọ ṣùgbọ́n owó tí o un wọlé kéré tí kò sì tó gbọ́ bùkátà látàrí èyí ó wà ọna miran ti owó lè má gba wọlé, ní àkókò yí ẹ̀gbọ́n baba Torimoro fe lọ sí oríle èdè Kamẹrúùnù fún ìṣe Taiwo sì tẹ le lọ bo yà ọ̀nà yí ọ sí.
Ní ọdún 1950, Bàbá alàjọ sómólú nígbàti o dé orílè èdè Kamẹrúùnù, bàbá alàjọ sómólú  wòó pé kini ohun lè má ṣe, ṣùgbọ́n Ọlọ́run fún bàbá náà ni ẹ̀bùn ìṣe lèyí tí ó sì mú lo. Bàbá náà ṣe onírúurú isẹ ni orílẹ̀ èdè Kamẹrúùnù bí àpẹẹrẹ ó tà ìwé ìròyìn,ó ṣe òwò káràkátà. Bàbá alàjọ sómólú ni aládùúgbò tí jẹ́ wí pé isẹ àjo gbígbé ní ohun ṣe, tí bàbá náà sì fojú sí nítorí pé ó nife sì púpò púpò, ti o sí mọ. Ní ọdún 1954 bàbá sí padà sí orílè èdè Nàìjíríà lèyí tí ó ní lémi láti ma gba àjọ látàrí ohun tí ó kọ ní orílè èdè Kamẹrúùnù, ní gbogbo àkókò yí ọmọ ọdún Mókàndílóogójì ni bàbá jẹ́,
 kí ó sì tó kúrò ní orílè èdè Kamẹrúùnù ó ṣe ẹ dá ìwé tí yíò ma ko orúkọ àwọn ènìyàn sì tí ó pe orúkọ rẹ ni alàjọ sómólú ojojumo.
Ṣùgbọ́n kí ó tó bẹ̀rẹ̀ ó lọ fi lọ ẹ̀gbọ́n bàbá tí ó sí sọ pé kí ó má ṣe látàrí àwọn tí ó ti ṣe sẹ́yìn tó jẹ́ wípé gbèsè ni wọn jẹ bo, kò gbo ohun tí ẹni yí sọ, ó tún lọ sọ fún ẹ̀gbọ́n rẹ obìnrin, ẹ̀gbọ́n rẹ yí ni ó mú lọ sí odò olùṣọ́àgùntàn tí wọn sì gba àdúrà tí wọn sì ni ọ̀nà rẹ ni kí má ṣe ṣùgbọ́n wọn kii ni lọọ pé kí ó má fi òtítọ́ inú ṣe.
Nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ ó lọ sí odò àwọn ìyá l’oja gbogbo àwọn ó sì dá lóhùn wọn wípé tí yíò kowó àwọn sá lọ tí ó bá yá, ṣùgbọ́n baba alàjọ sómólú kò ko irewasì ọkàn, nígbà tí ó yá àwọn ìyá  l’oja bá fi owó àwọn ọmọ wọn dán wò lèyí tí òsì yege láti ìgbà náà ni wọn ti dá àjọ fún.
Bàbá alàjọ sómólú je akínkanjú ẹni tí ó mú ìṣe lọkunkundun. Ní àkókò  yí àwọn igba ènìyàn ni wọn dàjọ fún tí ki si kọ nkan nkan sílè tí ó bá sì di ìpárí oṣù bí wọn ṣe kó owó fún náà ni yio dá padà, nítorí èyí ni wón bá fún ní orúkọ
 #alàjọsómólútíógbaowóolówóigbaènìyàntíkòsisekoorúkọwọnsílètíkòsiowókófúnẹnikẹ́ni.
Ní bí ti orí bàbá yí pé de awọn ènìyàn a máa sọ wípé “Orí ẹ pé bíi ti alàjọ Sómólú , tó fo didi ọdún mẹ́ta gbàjọ lai ko orúkọ ẹni kánkán sílè , tí kò sì siwo san fẹnikẹ́ni”,
Àwọn míràn a sì máa sọ pé”Orí ẹ pé bíi Alàjọ Sómólú , tó ta mótò ,tó fi ra kẹkẹ”, Ìdí tí wọn fi sọ èyí ni pé bàbá gba àjọ ó jèrè, ó kọ ilé rẹpẹtẹ, ó sì ra ọkọ̀,
ṣùgbọ́n ti ó bá gun ọkọ̀ naa fún ìgbà díè, tó bá ti wá yọnu, bàbá ó taa yio sì lọ fi owó náa ra kẹkẹ èyí wá jẹ́ ìyàlẹ́nu fún gbogbo àwọn ènìyàn pé irú Àkàndá ẹ̀yán wo rèé tí yíò lọ tá ọkọ̀ tí wá lọ fi ra kẹkẹ, èyí tún mú kí àwọn ènìyàn nífẹ̀ẹ́ bàbá gidigidi. Àwọn òní baara bàbá náà si ti mọ tí wọn ba tí rí kẹkẹ tuntun wọn tí mọ pé bàbá tún ti ta moto nìyẹn,ìdí rẹ rèé tí wọn fi má ń sọ pé “#Orí ẹ pé bíi Alàjọ Sómólú , tó ta mótò ,tó fi ra kẹkẹ”,
Bàbá gba àjọ fún bíi ogun ọdún, àgbà dee bàbá ó sile jáde lọ gba àjọ mọ ṣùgbọ́n àwọn oní baara tí ó nífẹ̀ẹ́ bàbá má ń mú owó àjọ wọn wá sí ilé, bàbá kọ ìyàwó ọmọ rẹ bí wọn ṣe ń ṣe iṣẹ́ náà, tí ó sì jẹ pé òhun náà lọ má ń gba àjọ lọ́wọ́ àwọn ni baara wọn.
Bàbá kú ní ẹni ọdún mẹ́tadílọgọrun(97) ni ọjọ́ kọkànlá oṣù kẹjọ ọdún 2012 ni ilé rèé tó wà ní sómólú ni ilu Èkó.
Bàbá alàjọ sómólú je ẹniti a ko gbọdọ̀ gbàgbé ní orílè èdè Nàìjíríà,awa ọdọ òní náà ni lati kọ ẹ̀kọ́ kan tàbí òmíràn nínú igbe ayé bàbá yí.

Leave a Reply

Your email address will not be published.