Òkèmẹ̀sí jẹ́ ilu kan ní ìlú Èkìtì, àwọn ìdí ilé kan wa ní Òkèmẹ̀sí tí òwe yìí tí wá tí wọn kìí jẹ IRÚ. Wọn a má ń sọ wípé IRÚ jọ Égbon, nítorí náà Égbon ni wọ́n má ń pe IRÚ. Ní ọjọ́ kan ìyá kan tí ó ń ta Irú lọ sí Òkèmẹ̀sí láti ta Irú rẹ̀. Láì mọ̀ wípé àwọn ìdílé tí kìí jẹ Irú ni ohun pàdé. Ìyá yìí bi wọ́n wí pé ibo ni ọjà wọn wà kí ohun lè lọ ta ọjà òun, ọkùnrin kan bá bíi wípé Kíni ohun tà ó bá sọ fún arákùnrin yìí wípé IRÚ ni ohun tà ẹ̀sẹ̀kesẹ̀ ni ọkùnrin náà fi ọwọ́ bo imú tí ó sì sọ wípé àwọn kìí jẹ égbon. Bẹ́ẹ̀ ni ìyá yìí sọ wípé Haaa láti ìgbà tí ohun ti ń ta Irú òun , òun ò kan àbùkù rí àfi ìgbà tí òun dé Òkèmẹ̀sí tí wọ́n pe IRÚ tí òun tà ní Égbon.
Ìdí rèé tí wọ́n fi máa ń pa òwe wípé:
“IRÚ NÍ ÒUN KÒ KAN ÀBÙKÙ RÍ ÀFI ÌGBÀ TÍ ÒUN DÉ ÒKÈMẸ̀SÍ TÍ WỌ́N PE ÒUN NÍ ÉGBON.”
#EdeYorubaRewa