ÌWÀ
Tọju ìwà rẹ ọ̀rẹ́ mí,
Ọlá a máa tàn nílé ẹni,
Ẹwà ási máa lọ lára ènìyàn,
Ṣùgbọ́n ìwà ní o ku ní kú nígbà abádé inú saare, Èéfín nìwà kò sì bí a ṣe bo ti ko ni’ru,
Ènìyàn gbé òkèèrè nìyí,
Rírìn sú mọ ní làá mọ ṣe ẹni,
Ìwà kí sì fí oníwà sílè,
Ìwà tí a wò ní yíò sọ orúkọ tí ayé a máa pe ni,
Ara sún wọn o fẹ aṣọ,
Ẹsẹ̀ sún wọn o nílò bàtà,
Bí ènìyàn bá dára tí kò ní wa,
Ó sọ ohun ribiribi nù,
Ìwà rere lèsó ènìyàn,
Sùúrù bàbà ìwà,
O jẹ́ tètè tọju ìwà rẹ ọrẹ wa.
Ìwà réré lè sọ ènìyàn