ỌMỌDÉ
Ewúré o mọlé olódì,
Bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ ọmọdé rí,
Bí a bá na ewúré,
A gbo etí nù pépé,
Ó tún padà síbi tí ó ti jìyà,
Ọmọdé ò mọlé olódì,
Ọmọdé ò lọ́tàá,
Bí wọ́n bá bára wọn jà,
Níbi tí wọ́n tí n ṣeré,
Láàrin ìṣẹ́jú méjì péré,
Ìjà ti tán,
Wọ́n tún ti ń bára wọn ṣeré padà,
Ọmọdé ò ládìsínú,
Inú ọmọdé mọ́,
Ó ju mimọ gan an lọ,
Àyà ọmọdé nkọ?
Ńṣe lo mọ́ karada,
Ko kí ẹnìkan níbí,
Báwo ni kì bá ṣe dùn tó bí àwọn àgbà bá leè ṣe bí ọmọdé,
Báwo ni ilẹ̀ ayé í bá ṣe dùn tó,
Ọmọdé ma dára ooo…..
Èdùmàrè fún wa lọmọ tio jáfáfá ,ma fún wa lọmọ alárè.
Àmín Àṣẹ Èdùmàrè