Apá kejì OTUA MÉJÌ
Ó di wí pé
Bí ẹnìkán bá ń sọ ọmọ lórúkọ
Àwọn ọmọ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ó lọ síbẹ̀.
Bí òkú kú fún ẹnìkan,
Wọn á ránńṣẹ́ pè wọ́n.
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ náàá ṣe
Tí wọn fi ń dárà gbogbo.
Ìgbà tí wọ́n dàgbà tán,
Tí àwọn náàá bímọ,
Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọmọ wọ́n ń ṣe.
Ijó ni wọ́n ń jó,
Ayọ̀ ni wọ́n ń yọ̀;
Wọ́n ní bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́
Ni awo àwọn ń ṣẹnu rereé pefá.
Wútùwútù yáákí;
Wútùwútù yám̀bèlé,
Ká súré pátápirá,
Ká fẹ̀wù àlàárì fọnkun àmọ́di,
Lékèélékèé, ẹyẹ ìmọ̀le,
Bó bá ṣí lórí ọ̀pọ̀tọ̀,
A bà sórí òrom̀bó,
A máa fi gbogbo ara kéwú eléwú kiri;
A díá fún ọ̀rúnmìlà,
Ifa ń sunkún òun ò rọ́mọ bí.
Wọ́n ní ó káakí Mọlẹ̀
Ó jàre,
Ẹbọ ní ó ṣe.
Ó gbọ́ rírú ẹbọ,
Ó rú
Ó gbọ́ èrù àtùkèṣù,
Ó rú
Ó gbọ́ ìkarara,
Ẹbọ́ ha fún un.
Ire mẹ́ta làwá ń wá:
Àwá ń wówó o,
Àwá ń wọ́mọ;
Àwá ń wá àtubọ̀tán ayé
1.Wútùwútù yáákí;Wútùwútù yám̀bèlé; This is to mimic The Muslims as their Arabic recitations sound to the hearing of those that do not know about them.
2. Lékèélékèé, ẹyẹ ìmọ̀le: The Muslims like white garment like that of a type of bird called Lékèélékèé
3. Gánḿbí: Muslim Name
4. Kálítù: Muslim Name
5. Dáúdù: Muslim Name
6. Wọ́n na igi mẹ́rin sílẹ̀ níbùúníbùú: That is how Muslims prepare their mosque at initial stage