ÌFẸ́

ÌFẸ́

Ìfé jé ohun àrà tí Olórun da tí ó gbódò máa joba láàrin omo ènìyàn nítorí láì sìí ìfé, aiyé kò le rójú. Ìfé ni ó lè se ohun gbogbo. Olódùmarè fé kí á máa lo Ìfé ni Ó se sẹ̀dá Ìfé. Láìsí Ìfé, ayé kò le dùn, ayé kò lè rójú, ayé a dàbí àsán(bí obè tí kò léran), ayé a dàbíi kòròfo ìsáná . Ìdùnnú a sì jìnà sọ́mọ́ ènìyàn.

Fún àpèrè, bí kò bá sí Ìfé láàrin ọkọ àti ìyàwó, inú ilé wọn kò lè rọgbọ.  Ọkọ kò ní gbádùn béèni ìyàwó kò ní sinmi. Àwon omo won gan, ọ̀rọ̀ won ó ní yé ara won. Ní ìgbèyìn omo á di omo olómo, ìyàwó á di ti elòmíràn, ọkọ a di bámìíì. Olórun tó dáwa ti mò pé a nilò Ìfé ló fi dá a sáàrin wa sùgbọ́n a ní láti fi àyè gbà á nípá fífi Ìfé hàn sí ara wa.

Bí Ìfé bá joba ní ilé-isé kan, á dàbí wí pé gbogbo won ló mọ isẹ́ se, ìfowósowópò won á túnbò máa mú ìgbéga bá ilé-isé náà. Bí ó bájé àárín ìlú kan ni Ìfé wà, ìlú náà á tòrò bíi omi afòwúròpon.  Eku a máà ké bíi eku, ẹyẹ á máa ké bíi eye, omo ènìyàn á máa fohùn bíi ọmọ ènìyàn. Àgàgà tó bá jé àárín olólùfé méjì ni Ìfé òtító wà, èyí á mú won lára dá, kò sì ní fi ààyè gba ohunkóhun tí ó lè da àárín won rú.

Orísirísi ìfé lówà

Ìfé Eléyelé: Àwòn ìfé báyìí, kìí jà, wón kì ya ara won, bó ti wù kórí. Yoruba bo, won ni eleye ki ba onile mu, ba onile je, ki o wa di ojo isoro ko yeri.  Eye to meto imule, ti o to eyele kosi. Eni eyele ba ba mule, o tun dorun alakeji. Eji lore dun, leyele se n fómo re bi meji

Ìfé Àìsètàn: Ìrúfé ìfé yìí kìí fi òrò pamó fún ara won. Tí a bá tilè rí eni ti ófè túwonká nípa sísó òrò won láburú fún enìkejì, òfo ni irú eni bé e má a mú bò. Ìfé tí kò lópin ni Ìfé yìí,  ìdí nìyí tí wón fi ń pèé ní Ìfé àìsètàn(tí ò le tán)

Ìfẹ́ dábènyànko: A tún le pè é ní ìfé e ètàn” nítorí ìfé ojú lásán ni eni tó bá nífèé dábènyànko máa ń bá enì kejì rè se.  Irúfé ìfẹ́ yìí síì wípé, “Mú obè (stew) wà á, kí enìkejì náà mú èko(solid pap).ìfé yìí kò jinná dénú, nítorí ìdí kan pàtó tí irú ìfẹ́ yen fi má a ń wáyé. Ó le jé nítorí wípé, okùnrin yen ní owó, obìnrin náà sì jé gbajúmò ní àwùjo, àwon méjèèjì wá ní ìfé ara won. Béè sì ni, bí ilìsòro kan bá dìde sí òkan lára eni tí ó ńse irú ìfé yìí, wón máa fi ara won sílè nítorí kò sí Ìfe gidi tí ó le mú kí ìkejì rè Fara da ìsòro náà.. Tí ó sì jépé àwon Yorùbá máa ń pa ówe pé “Ìgbà ìpónjú làá mo òré””.

Ìfé orí ahón:  ìfé báyìí kìi se ìfé gidi. Ìfé orí ahón jé ìfé tí òkan lára àwon olólùfé yìí kò nífèé enìkejì dénú.  Atún leè pe irú ìfẹ́ yìí ní ìfẹ́ ètànje. Èyin ò gbó bí wọ́n ti wí ni? Wón ní Ìfé ni àkójá òfin, tí Ìfé bá wà, Àánú , Ayò àti ohun gbogbo dáradára mìíràn ló máa tè le.

Ìmòràn sí gbogbo àwon olólùfẹ́ wa àti gbogbo ojú tí ó ń ka àpilèko yìí ni wí pé, kí é jé kí á fi Ìfé lò ni ibi gbogbo tí a bá ti bá ara wa láì fi ẹ̀sìn tàbí ẹ̀yà se. Ìfẹ́ òtítọ́ ni ó lè mú wa la ayé já pẹ̀lú ìrọ̀rùn. Ìfẹ́ se pàtàkì, Ó se kókó. Ibi tí ìfẹ́ bá wà ni àlàáfíà gbé ń joba. Ire á jẹ́ tiwa nígbà gbogbo.

ÒFO ÌFẸ́

Dúró ń bẹ̀”
Ohun tá a wí f’ọ́gbọ́
Lọ́gbọ́ ń gbọ́
Èyí tá a wí f’ọ́gbà
Lọgbà ń gbà
Inú ẹtù kìí dùn
Kó wálé ọdún
Inú àgbọ̀nrín kìí dùn
Kò wálé dìsẹ́nbà
Aṣọ ìbora kìí lápò
Kèké kìí ya ilé epo
Ìgbín kìí fẹ́yìn rìn
Ọ̀kadà kìí ní kọ̀ndọ́
Ijọ́ tí ọmọdé bá gbé’rà lóko
Ní dé ilé
Ijọ́ tókèlé ba dọ́nà ọ̀fun
Ní I de ikùn
Mo pàṣẹ fún ọ
Óyá!!! Fi àtẹ̀jíṣé yìí ránṣé
Ẹ̀fẹ̀ lèyí àbí àwàdà.

Leave a Reply

Your email address will not be published.