ORÍ

ORÍ

Orí àpéré àtété níran,
Àtètè gbeni kù f’òsà,
Orí mi gbèmí,
Orí mi gbémi dé ibire,
Orí mi gbémi dé ibi ayọ̀ mi,
Ṣe bí orí ni gbéni taa dádé owó,
Orí yìí kan náà ni gbéni taa wo èjìgbà’lẹ̀kẹ̀,
Àtètè dáyé òkan t’ ẹ̀gbọ́n,ẹni orí bá gbè ni sere,
Bí orí bá gbeni wọn á ní olúwaarè ṣe Ògùn ni,
Orí là bá bọ ká fi òrìṣà sílè,
Orí mi gbèmí,
orí mi má gb’àbọ̀dè,
Orí ìwọ náà má gb’àbọ̀dè,
Orí tẹ̀yin gbogbo olólùfẹ́ #ÈdèYorùbáRewà náà ò ní gb’àbọ̀dè.
Gbogbo ibití á tí ṣe rere, kí orí èmi àti ìwọ má sai mú wá dé’bẹ̀.
Àṣẹ Èdùmàrè

Leave a Reply

Your email address will not be published.