A B D Olówe

A______ Àgbà kìí wà lọ́jà, k’órí ọmọ tuntun ó wó.
B______ Bá mi na ọmọ mi, kò dénu ọlọ́mọ.
D______ Dídà ló  dà l’ọmọ dé ẹ̀gbẹ́, ẹ̀gbẹ́ kìí ṣe ilé ọmọ.
E_____ Ènìyàn ló ń bẹ nìdí oró l’oró ń ké.
Ẹ____Ẹ̀dá tó mo ìṣe òkùnkùn, kó má ṣe d’òṣùpá l’oró
F_____ Fálànà gbọ́ tìẹ , t’ara eni làá gbọ́.
G_____ Gìrìpà kò sí ilẹ̀kùn, ẹni tó bá ní kọ́kọ́rọ́ lo ń si.
Gb____ Gbangba d’ẹkùn , kedere bẹ́ẹ̀ wò.
I______ Iyán ogún odún,a máa jó ni lówó felifeli
H_____ Honti-honti kó l’eyín , b’eyín bá jẹ́ méjì, kó sáà funfun.
J_____ Jàkùmò kìí rìn‘de ọ̀sán,ẹni a bíi re kìí rìn‘ru.
K______ Kí obìnrin to àtòrìn,Kí Ọkùnrin to àtòrìn,ká wo ẹni tí ó ma lómi léyìn ẹsẹ̀ ju ara wọn lo.
L_____ Láaláa tó r’òkè , ilè ni ń bọ̀.
M_____ Mo dàgbà nkọ̀ S’oge mó , owó ni kò sí.
N_____ Níbití erin méjì bá ti ń jà, koríko ibè kò ní gbé rí mó.
O_____ Orí tí yóò gbeni ní gbé aláwo ‘re ko ni
Ọ_____ Ọlọ́pà èwo ni tèpè,amúni ń jẹ́ amúni.
P_____Pàṣán ológìnní, kò sí lọ́wọ́ èkúté.
R_____Rírò ni t’ènìyàn , ṣíṣe ni ti Ọlọ́run.
S_____ Sàsà ènìyàn ló ń fẹ́ ni lẹ́yìn bí a ó bá sí ní ilé, t’ẹrú t’ọmọ ló ń fẹ́ ni lójú ẹni.
ṣ______Ṣàkátápàrá làá síntọ́, ojú àfọ́ọ̀fọ́tán, ìjà lón dá sílẹ̀
T______ Tí a bá kì f’awo, awo á kì  f’ọ̀gbèri .
U______
W_____WÈRÈ dùn wò, kò ṣeé bí lọmọ.
Y______Yin ni, yin ni, k’ẹni leè ṣe òmíràn.

Leave a Reply

Your email address will not be published.