Àlọ́ Àpagbè – Ìjàpá Ati Ẹyẹ Àdàbà

Èyí ni Àlọ́ àpagbè fún gbogbo olólùfẹ́ ojú ìwé yìí, mọ lérò wípé ẹ ò gbádùn ẹ.
Àlọ́ oooo
Àlọ́ ọọọọ
Àlọ́ yìí dá lórí Ìjàpá ati ẹyẹ Àdàbà
Gégé Bí ẹ̀yin náà ti mọ̀, alàgàbàgebè ni Ìjàpá, olè àti ọ̀kánjúwà ni pẹ̀lú. Ní ayé àtijó, Ìjàpá àti Ẹyẹ Àdàbà jọ ń ṣe ọ̀rẹ́. Àdàbà ni ẹṣin kan tí ó máa ń gùn kiri tí Ìjàpá kò sì ní nǹkankan. Ìjàpá ronú lọ́jọ́ kan, ó sì gbèrò bí yóò ti ṣe pa ẹṣin Àdàbà. Ó rí pé Àdàbà gbayì láàrin àwùjọ èyí tí kò dùn mọ̀ Ìjàpá nínú.
Nígbà tí ó di ọjọ́ kan Ìjàpá dá ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yín, ó pa ẹṣin Àdàbà. Àdàbà kò bínú sí kíkú tí ẹṣin rẹ̀ kú. Ohun tí ó ṣe ni pé ó gé orí ẹṣin náà ó bòó mọ́lẹ̀ ó wá fi ojú ẹṣin si ìta tí ènìyàn leè máa rí dáadáa. Bí Ìjàpá ti ń kọjá lọ ni ó rí ojú tí ó yọ síta. Eléyìí yàá lẹ́nu, kíá ó gbéra ó di ilé ọba. Nígbà tí ó dé ààfin, ó sọ fún ọba pé òun ti rí ibi tí ilé gbé lójú. Eléyìí ya ọba lẹ́nu, ó sì tún bí Ìjàpá bóyá ohun tí ó ń sọ dáa lójú. Ìjàpá sọ fún ọba pé ó dá òun lójú, ó sì tún wá fi dá ọba lójú pé bí kò bá rí bẹ́ẹ̀ kí ọba pa òun. Nígbà yìí ni ọba pe gbogbo àwọn ìjòyè àti ẹmẹ̀wà rẹ̀ pé kí àwọn lọ wo ibi tí ilẹ̀ gbé lójú. Ìjàpá ni ó síwájú tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ orin báyìí pé;
Ìjàpá___________ Mo ti rí ibi ilẹ̀ gbé lójú
Agberin________ Ilẹ̀
Ìjàpá___________ Mo ti rí ibi ilẹ̀ gbé lójú
Agberin________ Ilẹ̀
Báyìí ni gbogbo wọn ń dá reirei lọ sí ibi tí ilẹ̀ gbé lójú. Bí Àdàbà ti gbọ́ ohun tí Ìjàpá ṣe yìí ni ó bá sáré lọ sí ibi tí ó bo orí ẹṣin rẹ̀ tí ó wó sí, ni ó bá wú orí náà kúrò lọ sí ibòmíràn. Nígbà tí ọba ìjòyè àti àwọn ẹmẹ̀wà dé ibi tí Ìjàpá wí, wọn kò rí nǹkan kan Ìjàpá bẹ̀rẹ̀ sí tú ilẹ̀ kiri títí kò rí ojú kankan. Ìgbà yí ni ọba bínú gidigidi pé Ìjàpá pa irú irọ́ tí ó tó báyìí àti pé ó tún da òun, àwọn ìjòyè àti àwọn ẹmẹ̀wà láàmú láti wá wo ohun tí kò sí níbẹ̀. Kíá ni ọba pàṣẹ pé kí wọn ó ti ojú Ìjàpá yọ’dà kí wọn ó ṣì ti ẹ̀yìn rẹ̀ kì í bọ àkọ̀.Eléyìí jásí pé wọn paá. Báyìí ni Ìjàpá fi ìlara pa ara rẹ̀.
#EdeYorubaRewa

Leave a Reply

Your email address will not be published.