Ewì – Ìyá Ni Wúrà

Ìyá, 
kíni ọmọ le ṣé lálá sì ìyá?
Ìyá tí ó lóyún fún oṣù mẹsan,
Ní ìbẹ̀rẹ̀ oyún ìyá o le jẹ, kólé mú, kò lè sún bẹẹ ni ko leè wo,
Bí oyún ṣe ń dàgbà ní òun ti ńṣe ìyá yí padà ní gbà míràn oyún a sọ pé ìwọ ìyá yí jókòó,
 Bí ìyá kọọ ìnira dé, ipa pàtàkì ní ìyá kó lára ọmọ,
Bí ìyá tún bí ọmọ sáyé tán ìṣe ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀,
Bí orí fọ ọmọ ìyá lo nfo,
Bí ara dùn ọmọ ìyá lo ndun,
Bí ọmọ bá sunkún lọ gaju òru ìyá gbé sì ibadi yio sí má jo lairi ìlù,
Bi ọmọ sunkún jù wàá gbọ́ tí bàbá a wípé ọmọ rẹ sunkún dáa lóhùn,
ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìyá ní yio gba aaru kí ọmọ lè bá jẹ́ ènìyàn,
Wúrà tí owo kòlè rà ni ìyá jẹ́,
kò sì òun ti o leè ṣẹlẹ̀ ìyá mi ni ìyá mi,
Kódà kí o ma já itó ìyá mi ni ìyá mi,
Kódà bí ó má bu igi jẹ ìyá mi ìyá mi ni gbogbo ìgbà.
Ìyá ni wúrà iyebíye tí owó kò lè rà.
Kí Ẹlẹ́dàá jẹ kí gbogbo ìyá wá pé fún wá Àmín oooo
Àwọn tí wọn kò sì ní ìyá láyé mọ kí Èdùmàrè jogún ẹni tí yíò ṣe ìyá fún wọn.
(Àmín Àṣẹ Èdùmàrè)

Leave a Reply

Your email address will not be published.