Ewì – Bàbá Ni Jígí

Bàbá ni jígí
Bàbá ṣe pàtàkì lára ọmọ
Bàbá ṣe kókó,
Láìsí bàbá ìwọ ọmọ òlè dé inú ìyá rẹ
Bàbá ní pèsè oúnjẹ fún ìwọ àti ìyá rẹ
Láìsí bàbá ilé ò lè dùn
Bàbá dára
Bàbá ni jígí ọmọ
Bàbá ni ọmọ ń wo àwò kọ́ ṣe é,
Ọmọ tí a tó pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ bàbá irú wọn ní yàn tíì yanjú láwùjọ,
Mọ dúpẹ́ wípé mo ní bàbá tí ó fẹ́ràn ọmọ,
Èdùmàrè má PA bàbá wa, kí wọn PÉ láyé jẹun ọmọ.
Ọlọ́run fi ọrùn ké àwọn bàbá tí wọ́n tí KÚ
Ìyá ni wúrà
Baba ni jígí.
Èdùmàrè jẹ́ kí gbogbo òbí pé láyé nínú àlàáfíà àti ìdẹ̀ra.
Àmín Àṣẹ Èdùmàrè
#EdeYorubaRewa

Leave a Reply

Your email address will not be published.