Ìgbín àti Ìjàpá

Àlọ́ oooo
Àlọ̀ ọọọọ

Àlọ́ yìí dá lórí ìgbín àti Ìjàpá

Ní ayé àtijó, ìgbín àti Ìjàpá jọ ń ṣe ọ̀rẹ́. Ọ̀rẹ́ kòríkòsùn ni wọ́n ṣe. Gbogbo ìlú ló sì mọ̀ wọ́n papọ̀ pé ọ̀rẹ́ gidi ni wọ́n ń ṣe. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìwà Ìjàpátìrókò ọkọ yánníbo ọ̀dàlẹ̀ pátápátá ni.

Ní ìlú tí ìgbín àti Ìjàpá ń gbé, ìṣẹ̀lẹ̀ kan ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kan. Se ni òkìkí kàn pé ẹnìkan ti pa abukẹ́ Ọba. Ọsìn ni orúkọ oyè Ọba ìlú náà. Bí Ìjàpá tí gbọ́ pé àwọn kan ti pa abukẹ́ Ọsìn, ni ó bá lọ sí ọ̀dọ̀ Ọba láti lọ sọ fún un pé ọ̀rẹ́ òun ìgbín ni o pa abukẹ́ Ọsìn. Ọba bi Ìjàpá bóyá ohun tí ó sọ dáa lójú daadaa à bí eré ló ń ṣe.

Ìjàpá sọ fún ọba bí òun àti ìgbín ṣe jẹ́ ọ̀rẹ́ kòríkòsùn àti bí àwọn kì í ṣe fi nǹkan kan pamọ́ fún ara wọn. Ìjàpá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ìgbín fúnra rẹ̀ ló wá sọ fún òun pé òun ni òun pa abuké Ọsìn. Kíá ni Ọba ránṣé pé kí wọ́n ó lọ mú ìgbín wá. Wọ́n mú ní papámọ́ra wá sí ilé Ọba. Nígbà tí wọ́n mú dé ọ̀dọ̀ Ọba, Ọba bi ìgbín léèrè bóyá òun ni ó pa abúlé Ọba. Ìgbín dá Ọba lóhùn pé kì í ṣe òun ni òun pa abuké Ọba àti pé bí Ọba bá fẹ́ mọ ẹni tí ó pa abuké Ọba òun lè ràn Ọba lọ́wọ́ láti jẹ́ kí ó mọ ẹni tí ó pa á.

Nígbàtí Ọba gbọ́ báyìí, ó pàṣẹ pé kí wọ́n tú ìgbín ṣílẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n tú ìgbín sílẹ̀ tán, ó sọ fún Ọba pé láti mọ ẹni tí ó pa abuké Ọba wọ́n ní láti fún òun ní ẹṣin ńlá kan àti àwọn Onílù. Ọ̀rọ̀ yìí kò kọ́kọ́ yé Ọba ṣùgbọ́n nígbà tí ìgbín tí fọwọ́ sọ̀yà pé òun yíò fi ojú ẹni tí ó pa abuké Ọba hàn, Ọba kò Jáà níyàn ó ṣe bí ó ti wí. Ó fún ìgbín ni ẹṣin ńlá kan àti àwọn Onílù. Ìgbín gun orí ẹṣin, o sì ní kí àwọn Onílù ó máa lu ìlù tẹ́lẹ̀ òun báyìí pé:

Ìgbín _______ Ìgbín pa abuké Ọsìn
Elegbe ______ Gbonngúgbọn
Ìgbín ________ Ọba dá’gbín lọ́lá
Elegbe _______ Gbonngúgbọn
Ìgbín _________Ìgbín g’ ẹṣin rọ̀bọ̀tọ̀
Elegbe ________ Gbonngúgbọn
Ìgbín ________Ìgbín g’ ẹṣin rọ̀bọ̀tọ̀.
Elegbe ______Gbonngúgbọn

Báyìí ni Ìgbín bẹ̀rẹ̀ sí gun ẹṣin kiri tí ó gun ún yíká gbogbo ìlú. Nígbà tí Ìjàpá gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ inú rẹ̀ bàjé ó ń ronú pé òun ni ó yẹ kí Ọba dá lọ́lá torí òun ni òun pa abuké Ọba. Ìjàpá múra, ó di ilé Ọba. Nígbà tí ó dé ààfin Ọba, ó kí Ọba pẹ̀lú ìdọ̀bálẹ̀, ó sọ fún Ọba pé òun ni ó yẹ kí Ọba dá lọ́lá torí pé òun ni òun pa abuké Ọba. Ọba bíi léèrè bí òun ti ó sọ dáa lójú. O sì tún sọ fún Ọba pé òun ni òun yẹ fún ọlá tí Ọba dá Ìgbín torí pé òun ni òun pa abuké Ọba. Kíá ni Ọba ní kí àwọn ẹmẹ̀wà òun mú Ìjàpá kí wọ́n dìí tapá tẹsẹ̀ kí wọn ó ti ojú rẹ yọ idà, kí wọn sì ti ẹ̀yìn rẹ̀ tí bọ àkọ̀.

Báyìí ni Ìjàpá fi ẹ̀tanú àti ìwà ọ̀dàlẹ̀ pa ara rẹ̀ tí Ìgbín sì ń jẹ ayé rẹ̀ lọ níbi tí ó tutù títí di òní yìí.

Ìtàn yìí kọ́ wa wípé kò yẹ kí á máa ṣe ìlara ẹnìkejì wa.

Mo wa fi àsìkò yìí ro gbogbo àwọn ènìyàn ti ìwà wọn jọ tí Ìjàpá ki wón lọ yí padà.

#EdeYorubaRewa.

Leave a Reply

Your email address will not be published.