IRE

IRE

Ẹjẹ́ ké gb’ayé ṣe rere,
Ọjọ́ a kú làá dère,
Ènìyàn ò sunwòn láàyè,
Ǹjẹ́ a lè rí ohun gidi sọ nípa rẹ tó bá kú,
Àbí àwọn ènìyàn a máa sọ wípé àtún kú tún kú ẹ lọrun,
Ẹjẹ́ ká gb’ayé ṣe rere,
Kí ọmọ aráyé lee rí ohun tó dára sọ,
Ẹjẹ́ ká kó pa láti tún, ilé, ọ̀nà, ìlú, orílè èdè wa ṣe,
Kí a kó ipa pàtàkì láwùjo wa,
kí ọmọ aráyé lee sọ nípa wa dára dára tí a bá kú,
Ní tèmi ooo rere lè mi o ṣe,
N ò ní ṣe ìkà,
kí ọmọ aráyé lee sọ ohun gidi nípa mi.

Ìwo ń kọ?

#EdeYorubaRewa

Leave a Reply

Your email address will not be published.