AYÉ ṢÒRO

AYÉ ṢÒRO

Ayé ṣòro,
Ayé nira,
Ẹnu ti ayé fi sọ wípé nkan gún ní wọ́n á tún fi sọ wípé kò rí bẹẹ mọ́,
Ayé ní pe olè kówájà,
Ayé ní pe olóko kówámu,
Ayé se ilá ilákó,
Ayé se ikàn,
Ikàn wèwù ẹ̀jẹ̀,
Ohun tí ayé sọ ènìyàn dà ní wọn a fi bu ti o ba ya,
Ayé ò fẹ́ kákú
Bẹ́ẹ̀ni wọn fẹ́ ká rùn
Ènìyàn bí àparò lọmọ aráyé ńfẹ́,
Àparò pẹ̀lú aṣọ pípán,
Gbogbo ènìyàn ló fẹ́ kó dàbí ohun,
A buni je fẹ́ yisi ni ọmọ aráyé,
Ko si ohun ti a le ṣe láti tẹ ayé lọ́rùn,
A ó leè we òkun ayé ja ooo,
A bí ṣé ìwọ leè wẹ òkun ayé já ni? kówá sọ.

#ẸDákunẹjẹ́káṣọ́rafáyé

Ayé ò ní mú wa, mú ọmọ wa ooooo

Àmín ẹ pọọọọọ

Leave a Reply

Your email address will not be published.